16. ohun tí n óo ṣe sí yín nìyí: n óo rán ìbẹ̀rù si yín lójijì, àìsàn burúkú ati ibà tí ń bani lójú jẹ́ yóo bẹ́ sílẹ̀ láàrin yín, ẹ óo sì bẹ̀rẹ̀ sí kú sára. Bí ẹ bá gbin ohun ọ̀gbìn, òfò ni yóo jásí, nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóo jẹ ẹ́.
17. N óo kẹ̀yìn sí yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. Àwọn tí ẹ kórìíra ni yóo máa jọba lórí yín, ẹ óo sì máa sá nígbà tí ẹnikẹ́ni kò le yín.
18. “Bí mo bá ṣe gbogbo èyí, sibẹ tí ẹ kò gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.
19. Pẹlu gbogbo agbára tí ẹ ní, n óo tẹ̀ yín lórí ba; òjò yóo kọ̀, kò ní rọ̀, ilẹ̀ yóo sì le bí àpáta.
20. Iṣẹ́ àṣedànù ni ẹ óo máa ṣe, nítorí pé, ilẹ̀ kò ní mú ìbísí rẹ̀ wá, àwọn igi oko kò ní so.
21. “Bí ẹ bá lòdì sí mi, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi, n óo jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.
22. N óo da àwọn ẹranko burúkú sáàrin yín, tí yóo máa gbé yín lọ́mọ lọ, wọn yóo run àwọn ẹran ọ̀sìn yín, n óo dín yín kù, tí yóo fi jẹ́ pé ilẹ̀ yín yóo di ahoro.
23. “Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ ba kọ̀, ti ẹ kò yipada, ṣugbọn tí ẹ kẹ̀yìn sí mi,
24. èmi gan-an yóo wá kẹ̀yìn si yín, n óo sì jẹ yín níyà ní ìlọ́po meje, fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.
25. N óo fi ogun ko yín, tí yóo gbẹ̀san nítorí majẹmu mi. Bí ẹ bá sì kó ara yín jọ sinu àwọn ìlú olódi yín, n óo rán àjàkálẹ̀ àrùn sí ààrin yín, n óo sì fi yín lé àwọn ọ̀tá yín lọ́wọ́.