3. Ó ṣẹgun Hadadeseri, ọba Siria ní Soba, ní agbègbè ilẹ̀ Hamati, bí Hadadeseri tí ń lọ fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Yufurate.
4. Dafidi gba ẹgbẹrun (1,000) kẹ̀kẹ́ ogun, ẹẹdẹgbaarin (7,000) ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun lọ́wọ́ rẹ̀. Ó rọ́ àwọn ẹṣin náà lẹ́sẹ̀, ṣugbọn ó dá àwọn kan sí fún ọgọrun-un (100) kẹ̀kẹ́ ogun.
5. Nígbà tí àwọn ará Siria wá láti Damasku, láti ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi gbógun tì wọ́n, ó sì pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn.
6. Dafidi fi àwọn ọmọ ogun ṣọ́ Siria ti Damasku, àwọn ará Siria di iranṣẹ Dafidi, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.
7. Dafidi gba àwọn apata wúrà tí wọ́n wà lọ́wọ́ àwọn iranṣẹ Hadadeseri, ó kó wọn lọ sí Jerusalẹmu.
8. Ó kó ọpọlọpọ idẹ ní Tibihati ati Kuni, tí wọ́n wà lábẹ́ Hadadeseri. Idẹ yìí ni Solomoni fi ṣe agbada omi ńlá ati òpó ati àwọn ohun èlò idẹ fún ilé OLUWA.