14. N óo fi ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ ní ilé mi ati ninu ìjọba mi títí lae. N óo sì fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí lae.’ ”
15. Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ni Natani sọ fún Dafidi, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí i lójú ìran.
16. Dafidi bá lọ jókòó níwájú OLUWA, ó gbadura báyìí pé, “Kí ni èmi ati ilé mi jẹ́, tí o fi gbé mi dé ipò tí mo dé yìí?
17. Gbogbo èyí kò sì tó nǹkan lójú rẹ, Ọlọrun, o tún ṣèlérí nípa ìdílé èmi iranṣẹ rẹ fún ọjọ́ iwájú, o sì ti fi bí àwọn ìran tí ń bọ̀ yóo ti rí hàn mí, OLUWA Ọlọrun!
18. Kí ni mo tún lè sọ nípa iyì tí o bù fún èmi, iranṣẹ rẹ? Nítorí pé o mọ èmi iranṣẹ rẹ.
19. OLUWA, nítorí ti èmi iranṣẹ rẹ, ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ, ni o fi ṣe àwọn nǹkan ńlá wọnyi, tí o sì fi wọ́n hàn.
20. Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, OLUWA, kò sì sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn rẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ti fi etí wa gbọ́.
21. Ní gbogbo ayé, orílẹ̀-èdè wo ni ó tún dàbí Israẹli, àwọn eniyan rẹ, tí ìwọ Ọlọrun rà pada láti jẹ́ eniyan rẹ, tí o sì sọ orúkọ rẹ̀ di ńlá nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí o ṣe nígbà tí ó lé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn eniyan rẹ, tí o rà pada láti ilẹ̀ Ijipti?
22. O ti sọ àwọn eniyan rẹ, Israẹli, di tìrẹ títí lae, ìwọ OLUWA sì di Ọlọrun wọn.
23. “Nisinsinyii, OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí o sọ nípa èmi iranṣẹ rẹ ṣẹ, ati ti ìran mi lẹ́yìn ọ̀la, kí o sì ṣe bí o ti wí.