Kronika Kinni 15:3-14 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Nítorí náà, Dafidi pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sí Jerusalẹmu, kí wọ́n baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA wá sí ibi tí ó pèsè sílẹ̀ fún un.

4. Dafidi kó àwọn ọmọ Aaroni ati àwọn ọmọ Lefi jọ:

5. Iye àwọn ọmọ Lefi tí ó kó jọ láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: láti inú ìdílé Kohati: ọgọfa (120) ọkunrin, Urieli ni olórí wọn;

6. láti inú ìdílé Merari: igba ó lé ogún (220) ọkunrin, Asaaya ni olórí wọn,

7. láti inú ìdílé Geriṣomu, aadoje (130) ọkunrin, Joẹli ni olórí wọn;

8. láti inú ìdílé Elisafani, igba (200) ọkunrin, Ṣemaaya ni olórí wọn,

9. láti inú ìdílé Heburoni, ọgọrin ọkunrin, Elieli ni olórí wọn,

10. láti inú ìdílé Usieli, ọkunrin mejilelaadọfa (112), Aminadabu ni olórí wọn.

11. Dafidi pe Sadoku ati Abiatari, àwọn alufaa, pẹlu àwọn olórí àwọn ọmọ Lefi mẹfa, Urieli, Asaaya, ati Joẹli, Ṣemaaya, Elieli, ati Aminadabu,

12. ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí ìdílé yín ninu ẹ̀yà Lefi. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin ati àwọn eniyan yín, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli wá síbi tí mo ti tọ́jú sílẹ̀ fún un.

13. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé e lákọ̀ọ́kọ́, OLUWA Ọlọrun wa jẹ wá níyà, nítorí pé a kò tọ́jú rẹ̀ bí ó ti tọ́.”

14. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá ya ara wọn sí mímọ́ láti gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli.

Kronika Kinni 15