ó sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni olórí ìdílé yín ninu ẹ̀yà Lefi. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin ati àwọn eniyan yín, kí ẹ baà lè gbé Àpótí Majẹmu OLUWA Ọlọrun Israẹli wá síbi tí mo ti tọ́jú sílẹ̀ fún un.