24. Àwọn ohun tí Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ṣe nìyí, tí ó sọ ọ́ di olókìkí, yàtọ̀ sí ti àwọn akọni mẹta tí a sọ nípa wọn.
25. Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba.
26. Àwọn olókìkí mìíràn ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí: Asaheli, arakunrin Joabu; ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu;
27. Ṣamotu, láti Harodu;
28. Helesi, láti inú ìdílé Peloni, Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa, ati Abieseri, láti Anatoti
29. Sibekai, láti inú ìdílé Huṣati, ati Ilai, láti inú ìdílé Aho;
30. Maharai, ará Netofa, ati Helodi, ọmọ Baana, ará Netofa;
31. Itai, ọmọ Ribai, ará Gibea, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ati Bẹnaya, ará Piratoni;
32. Hurai, ará etí odò Gaaṣi, ati Abieli, ará Aribati;
33. Asimafeti, ará Bahurumu, ati Eliaba ará Ṣaaliboni;
34. Haṣemu, ará Gisoni, ati Jonatani, ọmọ Ṣagee, ará Harari;
35. Ahiamu, ọmọ Sakari, ará Harari, ati Elifali, ọmọ Uri;
36. Heferi, ará Mekerati, ati Ahija, ará Peloni;
37. Hesiro, ará Kamẹli, ati Naarai ọmọ Esibai;
38. Joẹli, arakunrin Natani, ati Mibihari, ọmọ Hagiri,
39. Seleki, ará Amoni, ati Naharai, ará Beeroti, tí ń ru ihamọra Joabu ọmọ Seruaya.