20. Abiṣai, arakunrin Joabu, ni olórí àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun. Ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀ òkìkí tirẹ̀ náà súnmọ́ ti àwọn akọni mẹta náà.
21. Òun ni ó lókìkí jùlọ ninu àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun náà, ó sì di olórí wọn; ṣugbọn kò ní òkìkí tó àwọn akọni mẹta.
22. Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, láti ìlú Kabiseeli, jẹ́ ọmọ ogun tí ó ti ṣe ọpọlọpọ ohun ìyanu, ó pa àwọn abàmì eniyan meji ará Moabu. Ó wọ ihò lọ pa kinniun kan ní ọjọ́ kan tí yìnyín bo ilẹ̀.
23. Ó pa ará Ijipti kan tí ó ga ju mita meji lọ. Ará Ijipti náà gbé ọ̀kọ̀ tí ó tóbi lọ́wọ́. Ṣugbọn kùmọ̀ ni Bẹnaya mú lọ́wọ́ lọ bá a, ó gba ọ̀kọ̀ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi pa á.
24. Àwọn ohun tí Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, ṣe nìyí, tí ó sọ ọ́ di olókìkí, yàtọ̀ sí ti àwọn akọni mẹta tí a sọ nípa wọn.
25. Ó di olókìkí láàrin àwọn ọgbọ̀n ọ̀gágun; ṣugbọn òkìkí tirẹ̀ kò tó ti àwọn akọni mẹta náà. Dafidi bá fi ṣe olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba.
26. Àwọn olókìkí mìíràn ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi nìwọ̀nyí: Asaheli, arakunrin Joabu; ati Elihanani, ọmọ Dodo, ará Bẹtilẹhẹmu;
27. Ṣamotu, láti Harodu;
28. Helesi, láti inú ìdílé Peloni, Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa, ati Abieseri, láti Anatoti
29. Sibekai, láti inú ìdílé Huṣati, ati Ilai, láti inú ìdílé Aho;
30. Maharai, ará Netofa, ati Helodi, ọmọ Baana, ará Netofa;