Kronika Keji 35:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Josaya ṣe Àjọ Ìrékọjá fún OLUWA ní Jerusalẹmu. Ní ọjọ́ kẹrinla, oṣù kinni ni wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá.

2. Ó yan àwọn alufaa sí ipò wọn, ó sì gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn ninu ilé OLUWA.

3. Ó sọ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń kọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́ pé, “Ẹ gbé Àpótí mímọ́ náà sinu ilé tí Solomoni ọmọ Dafidi, ọba Israẹli kọ́. Ẹ kò ní máa gbé e lé èjìká kiri mọ́. Ṣugbọn kí ẹ máa ṣiṣẹ́ fún OLUWA Ọlọrun, ati fún gbogbo eniyan Israẹli.

4. Ẹ kó ara yín jọ ní ìdílé ìdílé ati ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà Dafidi, ọba Israẹli ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.

5. Ẹ dúró ní ibi mímọ́, kí ẹ sì pín ara yín sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé àwọn arakunrin yín. Ìdílé kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ ní àwọn ọmọ Lefi tí wọn yóo wà pẹlu wọn.

Kronika Keji 35