1. Jehoṣafati ọmọ rẹ̀ ni ó jọba lẹ́yìn rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbáradì láti dojú ìjà kọ Israẹli.
2. Ó kó àwọn ọmọ ogun sí gbogbo àwọn ìlú olódi Juda, ó yan olórí ogun fún wọn ní ilẹ̀ Juda ati ní ilẹ̀ Efuraimu tí Asa baba rẹ̀ gbà.
3. OLUWA wà pẹlu Jehoṣafati nítorí pé ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbà ọ̀dọ̀ Dafidi, baba rẹ̀; kò sì bọ oriṣa Baali.