10. Ṣugbọn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí kò sì jẹ́ lásán lórí mí, nítorí mo ṣe akitiyan ju gbogbo àwọn aposteli yòókù lọ. Ṣugbọn kì í ṣe èmi tìkara mi, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tí ó wà pẹlu mi ni.
11. Nítorí náà, ìbáà ṣe èmi ni, tabi àwọn aposteli yòókù, bákan náà ni iwaasu wa, bẹ́ẹ̀ sì ni ohun tí ẹ gbàgbọ́.
12. Nígbà tí ó jẹ́ pé, à ń kéde pé Kristi jinde kúrò ninu òkú, báwo ni àwọn kan ninu yín ṣe wá ń wí pé kò sí ajinde òkú?
13. Bí kò bá sí ajinde òkú, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde.
14. Bí a kò bá jí Kristi dìde ninu òkú, a jẹ́ pé asán ni iwaasu wa, asán sì ni igbagbọ yín.
15. Tí ó bá jẹ́ pé a kò jí àwọn òkú dìde, a tún jẹ́ pé a purọ́ mọ́ Ọlọrun, nítorí a jẹ́rìí pé ó jí Kristi dìde, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jí i dìde.
16. Nítorí pé bí a kò bá jí àwọn òkú dìde, a jẹ́ pé a kò jí Kristi dìde.
17. Bí a kò bá sì jí Kristi dìde, a jẹ́ pé lásán ni igbagbọ yín, ẹ sì wà ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín sibẹ.
18. Tí ó bá wá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé àwọn onigbagbọ tí wọ́n ti kú ti ṣègbé!
19. Tí ó bá jẹ́ pé ninu ayé yìí nìkan ni a ní ìrètí ninu Kristi, àwa ni ẹni tí àwọn eniyan ìbá máa káàánú jùlọ!
20. Ṣugbọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ yìí ni pé a ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú, òun sì ni àkọ́bí ninu àwọn tí wọ́n kú.
21. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ eniyan ni ikú fi dé, nípasẹ̀ eniyan náà ni ajinde òkú fi dé.
22. Nítorí bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Adamu ni gbogbo eniyan ṣe kú, bẹ́ẹ̀ náà ni ó sì jẹ́ pé nípasẹ̀ Kristi ni a sọ gbogbo eniyan di alààyè.
23. Ṣugbọn a óo jí olukuluku dìde létòlétò: Kristi ni ẹni àkọ́kọ́, lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá farahàn, a óo jí àwọn tíí ṣe tirẹ̀ dìde.