1. Ará, mo fẹ́ ran yín létí ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, tí ẹ gbà, tí ẹ sì bá dúró.
2. Nípa ìyìn rere yìí ni a fi ń gbà yín là, tí ẹ bá dì mọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere tí mo fi waasu fun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ asán ni igbagbọ yín.
3. Nítorí ohun kinni tí ó ṣe pataki jùlọ tí èmi fúnra mi kọ́, tí mo sì fi kọ́ yín ni pé Kristi kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.
4. Ati pé a sin ín, a sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.
5. Ó fara han Peteru. Lẹ́yìn náà ó tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.
6. Lẹ́yìn náà ó tún fara han ẹẹdẹgbẹta (500) àwọn onigbagbọ lẹ́ẹ̀kan náà. Ọpọlọpọ ninu wọn wà títí di ìsinsìnyìí, ṣugbọn àwọn mìíràn ti kú.
51-52. Ẹ fetí sílẹ̀! Nǹkan àṣírí ni n óo sọ fun yín. Gbogbo wa kọ́ ni a óo kú, ṣugbọn nígbà tí fèrè ìkẹyìn bá dún, gbogbo wa ni a óo pa lára dà, kíá, bí ìgbà tí eniyan bá ṣẹ́jú. Nítorí fèrè yóo dún, a óo wá jí àwọn òkú dìde pẹlu ara tí kì í bàjẹ́, àwa náà yóo wá yipada.