2. Ẹ̀yin alára ni ìwé wa, tí a ti kọ sí ọkàn wa. Gbogbo eniyan ni wọ́n mọ ìwé yìí, tí wọ́n sì ń kà á.
3. Ó hàn gbangba pé ẹ̀yin ni ìwé tí Kristi kọ, tí ó fi rán wa. Kì í ṣe irú èyí tí wọ́n fi yíǹkì kọ, Ẹ̀mí Ọlọrun alààyè ni wọ́n fi kọ ọ́. Kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sí orí òkúta; ọkàn eniyan ni wọ́n kọ ọ́ sí.
4. A lè sọ èyí nítorí a ní igbẹkẹle ninu Ọlọrun nípa Kristi.
5. Kì í ṣe pé a ní agbára tó ninu ara wa, tabi pé a ti lè ṣe nǹkankan fúnra wa. Ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti ní gbogbo nǹkan ní ànító.
6. Ọlọrun ni ó mú kí á lè jẹ́ iranṣẹ ti majẹmu titun, tí kì í ṣe ti òfin tí a kọ bíkòṣe ti Ẹ̀mí. Nítorí ikú ni òfin tí a kọ sílẹ̀ ń mú wá, ṣugbọn majẹmu ti Ẹ̀mí ń sọ eniyan di alààyè.
7. Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀,
8. báwo ni iranṣẹ ti Ẹ̀mí yóo ti lógo tó?
9. Bí iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa lẹ́bi bá lógo, báwo ni iṣẹ́ tí à ń torí rẹ̀ dá wa láre yóo ti lógo tó?
10. Àní ohun tí ó lógo tẹ́lẹ̀ kò tún lógo mọ́ nítorí ohun mìíràn tí ògo tirẹ̀ ta á yọ.
11. Nítorí bí ohun tí yóo pada di asán bá lógo, mélòó-mélòó ni ti ohun tí yóo wà títí laelae?