1. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbà mí láyè kí n sọ̀rọ̀ díẹ̀ bí aṣiwèrè. Ẹ gbà mí láyè.
2. Mò ń jowú nítorí yín, bí Ọlọrun tií jowú. Nítorí èmi ni mo ṣe ètò láti fà yín fún Kristi bí ẹni fa wundia tí ó pé fún ọkọ rẹ̀.
3. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ẹ̀tàn má wọ inú ọkàn yín, tí ẹ óo fi yà kúrò ninu òtítọ́ ati ọkàn kan tí ẹ fi wà ninu Kristi, bí ejò ti fi àrékérekè rẹ̀ tan Efa jẹ.
4. Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà.
5. N kò rò pé mo kéré sí àwọn tí wọn ń pe ara wọn ní “aposteli” pataki wọnyi!
6. Ọ̀rọ̀ lè má dùn lẹ́nu mi, ṣugbọn mo ní ìmọ̀, ní ọ̀nà gbogbo a ti mú kí èyí hàn si yín ninu ohun gbogbo.
7. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ ni mo ṣẹ̀ tí mo fi ara mi sí ipò ìrẹ̀lẹ̀, kí ẹ lè ní ipò gíga? Àbí ẹ̀ṣẹ̀ ni, pé mo waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín láì gba nǹkankan lọ́wọ́ yín?
8. Mo fẹ́rẹ̀ jẹ àwọn ìjọ mìíràn run, tí mò ń gba owó lọ́wọ́ wọn láti ṣe iṣẹ́ fun yín.