Joṣua 19:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ilẹ̀ kẹta tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Sebuluni. Agbègbè tí ó jẹ́ ìpín tiwọn lọ títí dé Saridi.

11. Níbẹ̀ ni ààlà ilẹ̀ wọn ti yípo lọ sókè sí apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì wá sí apá ìlà oòrùn Jokineamu.

12. Láti Saridi, ààlà ilẹ̀ náà lọ sí òdìkejì, ní ìhà ìlà oòrùn, títí dé ààlà Kisiloti Tabori, láti ibẹ̀, ó lọ sí Daberati títí lọ sí Jafia;

13. láti Jafia, ó lọ sí apá ìlà oòrùn títí dé Gati Heferi ati Etikasini, nígbà tí ó dé Rimoni, ó yípo lọ sí apá Nea.

14. Ní apá ìhà àríwá, ààlà náà yípo lọ sí Hanatoni, ó sì pin sí àfonífojì Ifitaeli.

15. Ara àwọn ìlú tí ó wà níbẹ̀ ni, Kata, Nahalali, Ṣimironi, Idala, ati Bẹtilẹhẹmu, gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mejila.

16. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Sebuluni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

17. Ilẹ̀ kẹrin tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Isakari.

18. Lórí ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Jesireeli, Kesuloti, Ṣunemu;

19. Hafaraimu, Sihoni, Anaharati;

20. Rabiti, Kiṣioni, Ebesi;

21. Remeti, Enganimu, Enhada, ati Betipasesi.

22. Ààlà ilẹ̀ náà lọ kan Tabori, Ṣahasuma ati Beti Ṣemeṣi, kí ó tó lọ pin sí odò Jọdani. Gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrindinlogun.

Joṣua 19