6. Nígbà tí Simoni Peteru tí ó tẹ̀lé e dé, ó wọ inú ibojì lọ tààrà. Ó rí aṣọ-ọ̀gbọ̀ nílẹ̀,
7. ó rí aṣọ tí wọ́n fi wé orí òkú lọ́tọ̀, kò sí lára aṣọ-ọ̀gbọ̀, ó dá wà níbìkan ní wíwé.
8. Ọmọ-ẹ̀yìn keji tí ó kọ́kọ́ dé ẹnu ibojì náà bá wọ inú ibojì; òun náà rí i, ó wá gbàgbọ́.
9. (Nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kò tíì yé wọn pé dandan ni kí ó jí dìde ninu òkú.)
10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá tún pada lọ sí ilé wọn.
11. Ṣugbọn Maria dúró lóde lẹ́bàá ibojì, ó ń sunkún. Bí ó ti ń sunkún, ó bẹ̀rẹ̀ ó yọjú wo inú ibojì,
12. ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí.
13. Wọ́n bi í pé, “Obinrin, kí ló dé tí ò ń sunkún?”Ó dá wọn lóhùn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa mi lọ, n kò mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”
14. Bí ó ti sọ báyìí tán, ó bojú wẹ̀yìn, ó bá rí Jesu tí ó dúró, ṣugbọn kò mọ̀ pé òun ni.
15. Jesu bi í pé, “Obinrin, kí ní dé tí ò ń sunkún? Ta ni ò ń wá?”Maria ṣebí olùṣọ́gbà ni. Ó sọ fún un pé, “Alàgbà, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, kí n lè lọ gbé e.”
16. Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!”Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”)
17. Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ”
18. Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn.