8. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń hùwà ẹ̀ṣẹ̀, láti ọ̀dọ̀ Èṣù ni ó ti wá, nítorí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀. Nítorí èyí ni Ọmọ Ọlọrun ṣe wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run.
9. Gbogbo ẹni tí a bí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí irú-ọmọ Ọlọrun yóo máa gbé inú olúwarẹ̀, nítorí náà, kò ní máa dẹ́ṣẹ̀ nítorí a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
10. Ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ọmọ Ọlọrun yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù nìyí: gbogbo ẹni tí kò bá ṣe iṣẹ́ òdodo tí kò sì fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
11. Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ara wa.
12. Kí á má dàbí Kaini tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù, tí ó pa arakunrin rẹ̀. Kí ló dé tí ó fi pa á? Nítorí iṣẹ́ tirẹ̀ burú, ṣugbọn ti arakunrin rẹ̀ dára.
13. Ẹ má jẹ́ kí ẹnu yà yín bí ayé bá kórìíra yín.
14. Àwa mọ̀ pé a ti rékọjá láti inú ikú sí inú ìyè, nítorí a fẹ́ràn àwọn arakunrin. Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ wà ninu ikú.
15. Apànìyàn ni ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀. Ẹ sì ti mọ̀ pé kò sí apànìyàn kan tí ìyè ainipẹkun ń gbé inú rẹ̀.
16. Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.