Johanu Kinni 3:14-18 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Àwa mọ̀ pé a ti rékọjá láti inú ikú sí inú ìyè, nítorí a fẹ́ràn àwọn arakunrin. Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ wà ninu ikú.

15. Apànìyàn ni ẹnikẹ́ni tí ó bá kórìíra arakunrin rẹ̀. Ẹ sì ti mọ̀ pé kò sí apànìyàn kan tí ìyè ainipẹkun ń gbé inú rẹ̀.

16. Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.

17. Bí ẹnìkan bá ní dúkìá ayé yìí, tí ó rí arakunrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí kò ṣàánú rẹ̀, a ṣe lè wí pé ìfẹ́ Ọlọrun ń gbé inú irú ẹni bẹ́ẹ̀?

18. Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ti ọ̀rọ̀ ẹnu tabi ti ètè lásán; ṣugbọn kí ó jẹ́ ti ìwà ati ti òtítọ́.

Johanu Kinni 3