Joẹli 3:5-13 BIBELI MIMỌ (BM)

5. nítorí ẹ ti kó fadaka ati wúrà ati àwọn ìṣúra mi olówó iyebíye lọ sí ilé oriṣa yín.

6. Ẹ ta àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu fún àwọn ará Giriki, ẹ kó wọn jìnnà réré sí ilẹ̀ wọn.

7. Ṣugbọn nisinsinyii, n óo gbé wọn dìde níbi tí ẹ tà wọ́n sí, n óo sì gbẹ̀san ìwà yín lára ẹ̀yin alára.

8. N óo ta àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin lẹ́rú fún àwọn ará Juda. Wọn yóo sì tà wọ́n fún àwọn ará Sabea, orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré; nítorí OLUWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.”

9. Ẹ kéde èyí láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè.Ẹ múra ogun,ẹ rú àwọn akọni sókè.Kí gbogbo àwọn ọmọ ogun súnmọ́ tòsí,ogun yá!

10. Ẹ fi irin ọkọ́ yín rọ idà,ẹ fi dòjé yín rọ ọ̀kọ̀,kí àwọn tí wọn kò lágbára wí pé, “Ọmọ ogun ni mí.”

11. Ẹ yára, ẹ wá,gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí ẹ wà ní àyíká,ẹ parapọ̀ níbẹ̀.Rán àwọn ọmọ ogun rẹ wá, OLUWA.

12. Jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè dìde,kí wọ́n wá sí àfonífojì Jehoṣafati,nítorí níbẹ̀ ni n óo ti ṣe ìdájọ́ gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká.

13. Ẹ ti dòjé bọ oko, nítorí àkókò ìkórè ti tó,ẹ lọ fún ọtí waini nítorí ibi ìfúntí ti kún.Ìkòkò ọtí ti kún àkúnwọ́sílẹ̀,nítorí ìkà wọ́n pọ̀.

Joẹli 3