11. Nítorí ó mọ àwọn eniyan lásán,ṣé bí ó bá rí ẹ̀ṣẹ̀,kí ó má ṣe akiyesi rẹ̀?
12. Ó di ìgbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ọmọ rẹ̀ ní eniyan,kí òmùgọ̀ eniyan tó gbọ́n.
13. “Bí o bá fi ọkàn rẹ sí ohun tí ó tọ́,o óo lè nawọ́ sí i.
14. Bí o bá ń dẹ́ṣẹ̀, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́,má sì ṣe jẹ́ kí ìwà burúkú, wà ní ọwọ́ rẹ.
15. Nígbà náà ni o óo tó lè fi ìgboyà gbójú sókè láìlẹ́bi;o óo wà láìléwu,o kò sì ní bẹ̀rù.
16. O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ,nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀,yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ.
17. Ayé rẹ yóo mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ;òkùnkùn rẹ yóo sì dàbí òwúrọ̀.
18. Ọkàn rẹ óo balẹ̀, nítorí pé o ní ìrètí,a óo dáàbò bò ọ́, o óo sì sinmi láìséwu.
19. O óo sùn, láìsí ìdágìrì,ọpọlọpọ eniyan ni wọn óo sì máa wá ojurere rẹ.
20. Àwọn ẹni ibi óo pòfo;gbogbo ọ̀nà tí wọ́n lè gbà sá àsálàni yóo parẹ́ mọ́ wọn lójú,ikú ni yóo sì jẹ́ ìrètí wọn.”