Jeremaya 7:27-34 BIBELI MIMỌ (BM)

27. “Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn.

28. O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’

29. “Ẹ gé irun orí yín dànù,ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè,nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀,ó ti fi ibinu ta ìran yín nù.

30. “Àwọn ọmọ Juda ti ṣe nǹkan burúkú. Wọ́n gbé ère wọn kalẹ̀ ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́.

31. Wọ́n kọ́ pẹpẹ Tofeti ní àfonífojì Hinomu, wọ́n ń sun àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn níná níbẹ̀. N kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún wọn; irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ fi ìgbà kan sí lọ́kàn mi.

32. Nítorí náà nígbà tó bá yá, a kò ní pè é ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́, àfonífojì ìpànìyàn ni a óo sì máa pè é. Tofeti ni wọn yóo sì máa sin òkú sí nígbà tí kò bá sí ààyè ní ibòmíràn mọ́.

33. Òkú àwọn eniyan yìí yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati fún àwọn ẹranko, kò sì ní sí ẹni tí yóo lé wọn.

34. N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní Jerusalẹmu, a kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé níbẹ̀ mọ́; nítorí pé n óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro.

Jeremaya 7