1. OLUWA rán Jeremaya níṣẹ́, ó ní
2. kí Jeremaya dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, kí ó sì kéde pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé láti sin OLUWA.
3. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Ẹ tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe, kí n lè jẹ́ kí ẹ máa gbé ìhín.
4. Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí pé: “Tẹmpili OLUWA nìyí, kò séwu, tẹmpili OLUWA nìyí.”
5. “ ‘Bí ẹ bá tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ bá ń dá ẹjọ́ òtítọ́,
6. tí ẹ kò bá fi ìyà jẹ àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, tabi àwọn opó, tabi kí ẹ máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì máa bọ oriṣa káàkiri, kí ẹ fi kó bá ara yín,
7. n óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí títí lae, lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti ìgbà laelae.
8. “ ‘Ẹ wò ó! Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò lè mú èrè wá ni ẹ gbójú lé.
9. Ṣé ẹ fẹ́ máa jalè, kí ẹ máa pa eniyan, kí ẹ máa ṣe àgbèrè, kí ẹ máa búra èké, kí ẹ máa sun turari sí oriṣa Baali, kí ẹ máa bọ àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ káàkiri;
10. kí ẹ sì tún máa wá jọ́sìn níwájú mi ninu ilé yìí, ilé tí à ń fi orúkọ mi pè; kí ẹ máa wí pé, “OLUWA ti gbà wá là;” kí ẹ sì tún pada lọ máa ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí ẹ tí ń ṣe?
11. Ṣé lójú tiyín, ilé yìí, tí à ń fi orúkọ mi pè, ó ti wá di ibi ìsápamọ́ sí fún àwọn olè? Mo ti ri yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
12. Nisinsinyii, ẹ lọ sí ilé mi ní Ṣilo, níbi ìjọ́sìn mi àkọ́kọ́, kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i, nítorí ìwà burúkú Israẹli, àwọn eniyan mi.
13. Nisinsinyii, nítorí gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe wọnyi, tí mo sì ń ba yín sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́, tí ẹ kò gbọ́, tí mo pè yín, tí ẹ kò dáhùn,