17. Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ,wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ,wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin.Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín,ati àwọn mààlúù yín.Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín.Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.”
18. OLUWA ní, “Ṣugbọn sibẹ, ní gbogbo àkókò yìí, n kò ní pa yín run patapata,
19. nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.”
20. OLUWA ní, “Kéde rẹ̀ ní ilẹ̀ Jakọbu,sì ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ ní ilẹ̀ Juda:
21. Ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin òmùgọ̀, aláìlọ́gbọ́n,ẹ̀yin tí ẹ lójú, ṣugbọn tí ẹ kò ríran;ẹ létí, ṣugbọn tí ẹ kò gbọ́ràn.
22. Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín?Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè.Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun,tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé!Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan,kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.
23. Ṣugbọn ọkàn ẹ̀yin eniyan wọnyi le, ọlọ̀tẹ̀ sì ni yín.Ẹ ti yapa, ẹ sì ti ṣáko lọ.