Nítorí mo gbọ́ igbe kan, tí ó dàbí igbe obinrin tí ó ń rọbí,ó ń kérora bí aboyún tí ó ń rọbí alákọ̀ọ́bí.Mo gbọ́ igbe Jerusalẹmu tí ń pọ̀ọ̀kà ikú,tí ó na ọwọ́ rẹ̀ síta, tí ń ké pé,“Mo gbé! Mò ń kú lọ, lọ́wọ́ àwọn apànìyàn!”