Jeremaya 46:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sálọ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun kò lè sá àsálà.Ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate, ni wọ́n tí fẹsẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ṣubú.

7. Ta ló ń ru bí odò Naili yìí,bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀?

8. Ijipti ń ru bí odò Naili,bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀.Ijipti wí pé, ‘N óo kún, n óo sì bo ayé mọ́lẹ̀,n óo pa àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn run.

9. Ó yá, ẹṣin, ẹ gbéra,kí kẹ̀kẹ́ ogun máa sáré kíkankíkan!Kí àwọn ọmọ ogun máa nìṣó,àwọn ọmọ ogun Etiopia ati Puti, tí wọ́n mọ asà á lò,àwọn ọmọ ogun Ludi, tí wọ́n mọ ọfà á ta dáradára.’ ”

10. Ọjọ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ọjọ́ náà,ọjọ́ ẹ̀san, tí yóo gbẹ̀san ara rẹ̀ lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.Idà rẹ̀ yóo pa àpatẹ́rùn, yóo sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn ní àmuyó.Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní ń rúbọ,ní ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate.

11. Gòkè lọ sí Gileadi, kí o lọ wá ìwọ̀ra, ẹ̀yin ará Ijipti,asán ni gbogbo òògùn tí ẹ lò,ẹ kò ní rí ìwòsàn.

12. Àwọn orílẹ̀ èdè ti gbọ́ nípa ìtìjú yín,igbe yín ti gba ayé kan;nítorí àwọn ọmọ ogun ń rọ́ lu ara wọn;gbogbo wọn sì ṣubú papọ̀.

13. Ohun tí OLUWA sọ fún wolii Jeremaya nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni nígbà tí ó ń bọ̀ wá ṣẹgun ilẹ̀ Ijipti nìyí:

Jeremaya 46