34. Ẹ̀yin olùṣọ́-aguntan, ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ẹ kígbe. Ẹ̀yin oluwa àwọn agbo ẹran, ẹ máa yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú nítorí àkókò tí a óo pa yín, tí a óo sì tu yín ká ti tó, ẹ óo sì ṣubú lulẹ̀ bí ẹran àbọ́pa.
35. Kò ní sí ààbò mọ́ fún àwọn olùṣọ́-aguntan, kò ní sí ọ̀nà ati sá àsálà fún àwọn oluwa àwọn agbo ẹran.
36. Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-aguntanati ẹkún ẹ̀dùn ti àwọn oluwa agbo ẹran;nítorí OLUWA ń ba ibùjẹ ẹran wọn jẹ́.
37. Pápá oko tútù tí ìbẹ̀rù kò sí níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ti di ahoronítorí ibinu gbígbóná OLUWA.
38. Bíi kinniun tí ó fi ihò rẹ̀ sílẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fi àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀,ilẹ̀ wọn sì ti di ahoronítorí idà apanirun ati ibinu gbígbóná OLUWA.