Jeremaya 25:17-27 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Mo bá gba ife náà lọ́wọ́ OLUWA, mo sì fún gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLUWA rán mi sí mu:

18. Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí.

19. N óo fún Farao, ọba Ijipti mu, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀

20. ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu).

21. N óo fún Edomu mu, ati Moabu, ati àwọn ọmọ Amoni;

22. ati gbogbo àwọn ọba Tire, ati àwọn ọba Sidoni, ati gbogbo àwọn ọba erékùṣù tí ó wà ní òdìkejì òkun.

23. N óo fún Dedani mu, ati Tema, ati Busi ati gbogbo àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn.

24. N óo fún gbogbo àwọn ọba Arabia mu ati gbogbo àwọn ọba oríṣìíríṣìí ẹ̀yà tí wọn ń gbé aṣálẹ̀.

25. N óo fún gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Simiri mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Elamu ati gbogbo àwọn ti ilẹ̀ Media;

26. ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ àríwá, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn. N óo sì fún àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ ayé mu pẹlu. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ti mu tiwọn tán, ọba Babiloni yóo wá mu tirẹ̀.

27. OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí ẹ mu ọtí kí ẹ yó, kí ẹ sì máa bì, ẹ ṣubú lulẹ̀ kí ẹ má dìde mọ́; nítorí ogun tí n óo jẹ́ kí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin yín.

Jeremaya 25