Jeremaya 25:15-23 BIBELI MIMỌ (BM)

15. OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Gba ife ọtí ibinu yìí lọ́wọ́ mi, kí o fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí n óo rán ọ sí mu.

16. Wọn yóo mu ún, wọn yóo sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, wọn yóo máa ṣe bí aṣiwèrè nítorí ogun tí n óo rán sí ààrin wọn.”

17. Mo bá gba ife náà lọ́wọ́ OLUWA, mo sì fún gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLUWA rán mi sí mu:

18. Jerusalẹmu ati àwọn ìlú Juda, àwọn ọba ilẹ̀ Juda ati àwọn ìjòyè wọn, kí wọn lè di ahoro ati òkítì àlàpà, nǹkan àrípòṣé ati ohun tí à ń fi í ṣépè, bí ó ti rí ní òní yìí.

19. N óo fún Farao, ọba Ijipti mu, ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀

20. ati àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin wọn. N óo fún gbogbo àwọn ọba Usi mu, ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini, (Aṣikeloni, Gasa, Ekironi ati àwọn tí wọ́n kù ní Aṣidodu).

21. N óo fún Edomu mu, ati Moabu, ati àwọn ọmọ Amoni;

22. ati gbogbo àwọn ọba Tire, ati àwọn ọba Sidoni, ati gbogbo àwọn ọba erékùṣù tí ó wà ní òdìkejì òkun.

23. N óo fún Dedani mu, ati Tema, ati Busi ati gbogbo àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn.

Jeremaya 25