Jeremaya 23:36-40 BIBELI MIMỌ (BM)

36. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nuba ẹrù OLUWA mọ́. Nítorí pé èrò ọkàn olukuluku ni ẹrù OLUWA lójú ara rẹ̀; ẹ sì ń yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun alààyè po, ọ̀rọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wa.

37. Bí ẹ óo ti máa bèèrè lọ́wọ́ àwọn wolii ni pé, “Kí ni ìdáhùn tí OLUWA fún ọ?” Tabi, “Kí ni OLUWA wí?”

38. Ṣugbọn bí ẹ bá mẹ́nu ba “Ẹrù OLUWA,” lẹ́yìn tí mo ti ranṣẹ si yín pé ẹ kò gbọdọ̀ mẹ́nu bà á mọ́,

39. tìtorí rẹ̀, n óo sọ yín sókè, n óo sì gbe yín sọnù kúrò níwájú mi, àtẹ̀yin, àtìlú tí mo fi fún ẹ̀yin, ati àwọn baba ńlá yín.

40. N óo mú ẹ̀gàn ati ẹ̀sín ba yín, tí ẹ kò ní gbàgbé títí ayérayé.

Jeremaya 23