Jeremaya 23:29-33 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́?

30. Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbọ́ lẹ́nu ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi ni mo sọ ọ́.

31. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ ti ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

32. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

33. Bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi, tabi wolii kan, tabi alufaa kan, bá bi ọ́ léèrè pé, “Kí ni iṣẹ́ tí OLUWA rán?” Wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin gan-an ni ẹ jẹ́ ẹrù. OLUWA sì ní òun óo gbé yín sọnù.”

Jeremaya 23