Jeremaya 23:21-32 BIBELI MIMỌ (BM)

21. OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.

22. Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe.

23. “Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn?

24. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé?

25. Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá!

26. Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.

27. Wọ́n ṣebí àwọn lè fi àlá tí olukuluku wọn ń rọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀ mú àwọn eniyan mi gbàgbé orúkọ mi, bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé mi, tí wọn ń tẹ̀lé oriṣa Baali.

28. Kí àwọn wolii tí wọn lá àlá máa rọ́ àlá wọn, ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí ó sọ ọ́ pẹlu òtítọ́. Báwo ni a ṣe lè fi ìyàngbò wé ọkà?

29. Ṣebí bí iná ni ọ̀rọ̀ mi rí, ati bí òòlù irin tíí fọ́ àpáta sí wẹ́wẹ́?

30. Nítorí náà, mo dojú ìjà kọ àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọn gbọ́ lẹ́nu ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi ni mo sọ ọ́.

31. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ ọ̀rọ̀ ti ara wọn, tí wọn ń sọ pé èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

32. Mo lòdì sí àwọn wolii tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá irọ́, tí wọn ń rọ́ àlá irọ́ wọn, tí wọn fí ń ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà pẹlu irọ́ ati ìṣekúṣe wọn, nígbà tí n kò rán wọn níṣẹ́, tí n kò sì fún wọn láṣẹ. Nítorí náà wọn kò ṣe àwọn eniyan wọnyi ní anfaani kankan. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jeremaya 23