18. Mo ní, “Èwo ninu wọn ló wà ninu ìgbìmọ̀ OLUWA tí ó ti ṣe akiyesi tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Èwo ninu wọn ni ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì gbà á gbọ́?
19. Ẹ wo ibinu OLUWA bí ó ṣe ń jà bí ìjì! Ó ti fa ibinu yọ. Ó sì ń jà bí ìjì líle. Yóo tú dà sí orí àwọn eniyan burúkú.
20. Inú OLUWA kò ní rọ̀ títí yóo fi ṣe ohun tí ó pinnu lọ́kàn rẹ̀. Yóo ye wọn nígbà tí ọjọ́ ìkẹyìn bá dé.”
21. OLUWA ní, “N kò rán àwọn wolii níṣẹ́, sibẹsibẹ aré ni wọ́n ń sá lọ jíṣẹ́. N kò bá wọn sọ̀rọ̀, sibẹsibẹ wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
22. Bí wọn bá ti bá mi pé ní ìgbìmọ̀ ni, wọn ìbá kéde ọ̀rọ̀ mi fún àwọn eniyan mi, wọn ìbá yí wọn pada kúrò lọ́nà ibi tí wọn ń rìn, ati iṣẹ́ ibi tí wọn ń ṣe.
23. “Ṣé nítòsí nìkan ni mo ti jẹ́ Ọlọrun ni, èmi kì í ṣe Ọlọrun ọ̀nà jíjìn?
24. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé?
25. Mo gbọ́ ohun tí àwọn wolii tí wọn ń fi orúkọ mi sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ń sọ, tí wọn ń sọ pé, àwọn lá àlá, àwọn lá àlá!
26. Irọ́ yóo ti pẹ́ tó lọ́kàn àwọn wolii èké tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.