10. Ẹ̀yin ará Juda,ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú,ẹ má sì dárò rẹ̀.Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún,nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí.
11. Nítorí pé OLUWA sọ nípa Joahasi, ọba Juda, ọmọ Josaya, tí ó jọba dípò Josaya baba rẹ̀, tí ó sì jáde kúrò ní ibí yìí pé, “Kò ní pada sibẹ mọ́.
12. Ibi tí wọn mú un ní ìgbèkùn lọ ni yóo kú sí; kò ní fi ojú rí ilẹ̀ yìí mọ́.”
13. Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé,tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀.Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́,láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un.
14. Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé,“N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi,ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.”Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́.Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀,ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún.
15. Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba?Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni,tabi kò rí mu?Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo,ṣebí ó sì dára fún un.