Jeremaya 19:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ní kí n lọ ra ìgò amọ̀ kan, kí n mú díẹ̀ ninu àwọn àgbààgbà ìlú ati àwọn bíi mélòó kan ninu àwọn àgbà alufaa,

2. kí n lọ sí ìsàlẹ̀ àfonífojì ọmọ Hinomu, lẹ́nu Ibodè Àpáàdì; kí n sì kéde ọ̀rọ̀ tí òun óo sọ fún mi níbẹ̀:

3. “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọba Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ibi kan wá sórí ilẹ̀ yìí, híhó ni etí gbogbo àwọn tí wọn bá gbọ́ nípa rẹ̀ yóo máa hó.

Jeremaya 19