15. Wò ó! Wọ́n ń bi mí pé,“Níbo ni gbogbo ìhàlẹ̀ OLUWA já sí?Jẹ́ kí ó ṣẹ, kí á rí i!”
16. N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o rán ibi sí wọn,bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ ọjọ́ ibi fún wọn.OLUWA, o mọ̀ bẹ́ẹ̀.Ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde kò tún lè ṣàjèjì sí ọ.
17. Má di ohun ẹ̀rù fún mi,nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ ibi.
18. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi,ṣugbọn kí ojú má tì mí.Jẹ́ kí ìpayà bá wọn,ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà.Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa.
19. OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ dúró ní ẹnubodè Bẹnjamini níbí, tí àwọn ọba Juda máa ń gbà wọlé, tí wọn sìí gbà jáde; ati ní gbogbo ẹnubodè Jerusalẹmu,
20. kí o wí pé, ‘Ẹ gbọ́ bí OLUWA ti wí, ẹ̀yin ọba Juda, ati gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé.
21. OLUWA ní kí ẹ ṣọ́ra fún ẹ̀mí yín, ẹ má máa ru ẹrù ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ má gbé ẹrù wọ ẹnubodè Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.
22. Ẹ kò gbọdọ̀ ru ẹrù jáde ní ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ẹ níláti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, bí mo ti pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín.
23. Sibẹ àwọn baba yín kò gbọ́; wọn kò sì fetí sílẹ̀, wọ́n ṣe oríkunkun, kí wọn má baà gbọ́, kí wọn má baà gba ìtọ́ni.
24. Ṣugbọn bí ẹ̀yin bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò gbé ẹrù wọ inú ìlú yìí lọ́jọ́ ìsinmi, tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ láìṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà,