15. Nígbà tí Mahalaleli di ẹni ọdún marundinlaadọrin, ó bí Jaredi.
16. Lẹ́yìn tí ó bí Jaredi, ó gbé ẹgbẹrin ọdún ó lé ọgbọ̀n (830) láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
17. Gbogbo ọdún tí Mahalaleli gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó dín marun-un (895) kí ó tó kú.
18. Nígbà tí Jaredi di ẹni ọdún mejilelọgọjọ (162) ó bí Enọku.
19. Lẹ́yìn tí ó bí Enọku, ó gbé ẹgbẹrin (800) ọdún láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
20. Gbogbo ọdún tí Jaredi gbé láyé jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ọdún ó lé mejilelọgọta (962) kí ó tó kú.
21. Nígbà tí Enọku di ẹni ọdún marundinlaadọrin ó bí Metusela.
22. Lẹ́yìn tí ó bí Metusela, ó wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun fún ọọdunrun (300) ọdún, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
23. Gbogbo ọdún tí Enọku gbé láyé jẹ́ ọọdunrun ọdún ó lé marundinlaadọrin (365).
24. Enọku wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun, nígbà tí ó yá, wọn kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun mú un lọ.
25. Nígbà tí Metusela di ẹni ọgọsan-an ọdún ó lé meje (187) ó bí Lamẹki.