1. Nígbà tí ó yá, Adamu bá Efa, aya rẹ̀, lòpọ̀, ó lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní, “Pẹlu ìrànlọ́wọ́ OLUWA, mo ní ọmọkunrin kan,” ó sọ ọmọ náà ní Kaini.
2. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkunrin mìíràn, ó sọ ọ́ ní Abeli. Iṣẹ́ darandaran ni Abeli ń ṣe, Kaini sì jẹ́ àgbẹ̀.
3. Nígbà tí ó yá, Kaini mú ninu èso oko rẹ̀, ó fi rúbọ sí OLUWA.
4. Abeli náà mú àkọ́bí ọ̀kan ninu àwọn aguntan rẹ̀, ó pa á, ó sì fi ibi tí ó lọ́ràá, tí ó dára jùlọ lára rẹ̀ rúbọ sí OLUWA. Inú OLUWA dùn sí Abeli, ó sì gba ẹbọ rẹ̀,
5. ṣugbọn inú Ọlọrun kò dùn sí Kaini, kò sì gba ẹbọ rẹ̀. Inú bí Kaini, ó sì fa ojú ro.
6. OLUWA bá bi Kaini, ó ní, “Kí ló dé tí ò ń bínú, tí o sì fa ojú ro?
7. Bó bá jẹ́ pé o ṣe rere ni, ara rẹ ìbá yá gágá, ẹbọ rẹ yóo sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. Ṣugbọn nítorí pé ibi ni o ṣe, ẹ̀ṣẹ̀ ba dè ọ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ, ó fẹ́ jọba lé ọ lórí ṣugbọn tìrẹ ni láti ṣẹgun rẹ̀.”
8. Nígbà tí ó yá, Kaini pe Abeli lọ sinu oko. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, Kaini dìde sí Abeli àbúrò rẹ̀, ó sì lù ú pa.
9. OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”
10. OLUWA bá bi í pé “Kí ni o dánwò yìí? Láti inú ilẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ti ń kígbe pè mí.