7. Èmi pẹlu yín, a wà ní oko ní ọjọ́ kan, à ń di ìtí ọkà, mo rí i tí ìtí ọkà tèmi wà lóòró, ó dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì yí i ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún un.”
8. Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bi í pé, “Ṣé o rò pé ìwọ ni yóo jọba lórí wa ni? Tabi o óo máa pàṣẹ lé wa lórí?” Wọ́n sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i nítorí àlá tí ó lá ati nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
9. Ó tún lá àlá mìíràn, ó sì tún rọ́ ọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́, mo mà tún lá àlá mìíràn! Mo rí oòrùn, ati òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ mọkanla ní ojú àlá, gbogbo wọn foríbalẹ̀ fún mi.”
10. Nígbà tí ó rọ́ àlá náà fún baba rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Baba rẹ̀ bá a wí, ó ní, “Irú àlá rándanràndan wo ni ò ń lá wọnyi? Ṣé èmi, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ yóo wá foríbalẹ̀ fún ọ ni?”