26. Juda bá sọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Anfaani wo ni yóo jẹ́ fún wa bí a bá pa arakunrin wa, tí a sì bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀?
27. Ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣimaeli yìí. Ẹ má jẹ́ kí á pa á, nítorí arakunrin wa ni, ara kan náà ni wá.” Ọ̀rọ̀ náà sì dùn mọ́ àwọn arakunrin rẹ̀.
28. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn oníṣòwò ará Midiani ń rékọjá lọ, wọ́n bá fa Josẹfu jáde láti inú kànga gbígbẹ náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ará Iṣimaeli ní ogún owó fadaka. Àwọn ará Iṣimaeli sì mú Josẹfu lọ sí Ijipti.