12. N óo fún ọ ní ilẹ̀ tí mo fún Abrahamu ati Isaaki, àwọn ọmọ rẹ ni yóo sì jogún rẹ̀.”
13. Ọlọrun bá gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti bá a sọ̀rọ̀.
14. Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n òkúta kan nàró níbẹ̀, ó fi ohun mímu rúbọ lórí òkúta náà, ó ta òróró sórí rẹ̀,
15. Ó sì sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli.
16. Wọ́n kúrò ní Bẹtẹli, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Efurati ni ọmọ mú Rakẹli, ara sì ni ín gidigidi.
17. Bí ó ti ń rọbí lọ́wọ́, agbẹ̀bí tí ń gbẹ̀bí rẹ̀ ń dá a lọ́kàn le pé, “Má bẹ̀rù, ọkunrin ni o óo tún bí.”
18. Nígbà tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bọ́ lọ, kí ó tó kú, ó sọ ọmọ náà ní Benoni, ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹnjamini.
19. Bẹ́ẹ̀ ni Rakẹli ṣe kú, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà Efurati, èyí nnì ni Bẹtilẹhẹmu.
20. Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n kan nàró lórí ibojì rẹ̀, òun ni wọ́n ń pè ní ọ̀wọ̀n ibojì Rakẹli, ó sì wà níbẹ̀ títí di òní.
21. Jakọbu tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó pàgọ́ rẹ̀ sí òdìkejì ilé ìṣọ́ Ederi.