11. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí mo mú wá fún ọ nítorí pé Ọlọrun ti ṣe oore fún mi lọpọlọpọ ati pé mo ní ànító.” Jakọbu rọ̀ ọ́ títí tí ó fi gbà á.
12. Lẹ́yìn náà, Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jẹ́ kí á múra kí á máa lọ n óo sì ṣáájú.”
13. Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn, ó ní, “Ṣebí oluwa mi mọ̀ pé àwọn ọmọ kò lágbára tóbẹ́ẹ̀ ati pé mo níláti ro ti àwọn ẹran tí wọ́n ní ọmọ wẹ́wẹ́ lẹ́yìn, bí a bá dà wọ́n ní ìdàkudà ní ọjọ́ kan péré, gbogbo agbo ni yóo run.
14. Oluwa mi, máa lọ níwájú, n óo máa bọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ níwọ̀n bí ìrìn àwọn ẹran ati àwọn ọmọ bá ti lè yá mọ, títí tí n óo fi wá bá oluwa mi ní Seiri.”
15. Esau bá ní, “Jẹ́ kí n fi àwọn bíi mélòó kan sílẹ̀ pẹlu rẹ ninu àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi.” Ṣugbọn Jakọbu dá a lóhùn pé, “Mo dúpẹ́, má wulẹ̀ ṣe ìyọnu kankan. Àní, kí n ṣá ti rí ojurere oluwa mi.”
16. Esau bá yipada ní ọjọ́ náà, ó gbọ̀nà Seiri.
17. Ṣugbọn Jakọbu lọ sí Sukotu o kọ́ ilé kan fún ara rẹ̀ ó sì ṣe àtíbàbà fún àwọn ẹran rẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n Ṣe ń pe ibẹ̀ ní Sukotu.
18. Nígbà tí ó yá, Jakọbu dé sí Ṣekemu ní ilẹ̀ Kenaani ní alaafia, nígbà tí ó ń pada ti Padani-aramu bọ̀ ó pàgọ́ rẹ̀ siwaju ìlú náà.
19. Ó ra ilẹ̀ ibi tí ó pàgọ́ rẹ̀ sí ní ọgọrun-un (100) gẹsita lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, baba Ṣekemu.
20. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sọ pẹpẹ náà ní Eli-Ọlọrun-Israẹli.