1. Bí Jakọbu ti gbé ojú sókè, ó rí Esau tí ń bọ̀ pẹlu irinwo (400) ọkunrin. Ó bá pín àwọn ọmọ rẹ̀ fún Lea ati Rakẹli, ati àwọn iranṣẹbinrin mejeeji.
2. Ó ti àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn ṣáájú, Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì tẹ̀lé wọn, Rakẹli ati Josẹfu ni wọ́n wà lẹ́yìn patapata.
3. Jakọbu alára bá bọ́ siwaju gbogbo wọn, ó wólẹ̀ nígbà meje títí tí ó fi súnmọ́ Esau, arakunrin rẹ̀.
4. Esau sáré pàdé rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó so mọ́ ọn lọ́rùn, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, àwọn mejeeji sì sọkún.
5. Nígbà tí Esau gbé ojú sókè, tí ó rí àwọn obinrin ati àwọn ọmọ, ó ní, “Ta ni àwọn wọnyi tí wọ́n wà pẹlu rẹ?”Jakọbu dáhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ tí Ọlọrun fi ta èmi iranṣẹ rẹ lọ́rẹ ni.”
6. Àwọn iranṣẹbinrin ati àwọn ọmọ wọn bá súnmọ́ wọn, wọ́n sì wólẹ̀ fún Esau.
7. Lea ati àwọn ọmọ rẹ̀ náà súnmọ́ wọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un, lẹ́yìn náà ni Josẹfu ati Rakẹli súnmọ́ ọn, àwọn náà wólẹ̀ fún un bákan náà.