34. Labani bá dá a lóhùn pé, “Ó dára, ohun tí o wí gan-an ni a óo ṣe.”
35. Ṣugbọn ní ọjọ́ náà gan-an ni Labani ṣa gbogbo ewúrẹ́ ati òbúkọ tí àwọ̀ wọn ní funfun tóótòòtóó, tabi tí ó dàbí adíkálà, ati gbogbo àwọn tí wọ́n ní funfun lára, ati gbogbo àwọn aguntan dúdú, ó kó wọn lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́.
36. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ bá kó wọn lọ jìnnà sí Jakọbu, ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta. Jakọbu bá ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù.
37. Jakọbu gé ọ̀pá igi populari ati ti alimọndi, ati ti pilani tútù, ó bó àwọn ọ̀pá náà ní àbófín, ó jẹ́ kí funfun wọn hàn síta.
38. Ó to àwọn ọ̀pá wọnyi siwaju àwọn ẹran níbi tí wọ́n ti ń mu omi, nítorí pé, nígbà tí wọ́n bá wá mu omi ni wọ́n máa ń gùn.
39. Àwọn ẹran náà ń gun ara wọn níwájú àwọn ọ̀pá wọnyi, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bí ọmọ tí àwọ̀ wọn dàbí adíkálà ati àwọn tí wọ́n ní funfun tóótòòtóó.