17. Ọlọrun gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Lea, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin karun-un.
18. Lea ní “Ọlọrun san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo fún ọkọ mi ní iranṣẹbinrin mi.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Isakari.
19. Lea tún lóyún, ó bí ọkunrin kẹfa.
20. Ó ní, “Ọlọrun ti fi ẹ̀bùn rere fún mi, nígbà yìí ni ọkọ mi yóo tó bu ọlá fún mi, nítorí pé mo bí ọkunrin mẹfa fún un,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Sebuluni.
21. Lẹ́yìn náà, ó bí obinrin kan, ó sọ ọ́ ní Dina.
22. Lẹ́yìn náà ni Ọlọrun ranti Rakẹli, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣí inú rẹ̀.
23. Rakẹli lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan.
24. Ó wí pé, “Ọlọrun ti mú ẹ̀gàn mi kúrò,” ó sọ ọmọ náà ní Josẹfu; ó ní, “Kí OLUWA má ṣàì fún mi ní ọmọkunrin mìíràn.”
25. Lẹ́yìn tí Rakẹli bí Josẹfu, Jakọbu tọ Labani lọ, ó bẹ̀ ẹ́ pé “Jẹ́ kí n pada sí ilé mi.
26. Jẹ́ kí àwọn aya ati àwọn ọmọ mi máa bá mi lọ, nítorí wọn ni mo ṣe sìn ọ́. Jẹ́ kí n máa lọ, ìwọ náà ṣá mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ tó.”
27. Ṣugbọn Labani dá a lóhùn pé, “Gbà mí láàyè kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí, mo ti ṣe àyẹ̀wò, mo sì ti rí i pé nítorí tìrẹ ni OLUWA ṣe bukun mi,
28. sọ iye tí o bá fẹ́ máa gbà, n óo sì máa san án fún ọ.”
29. Jakọbu bá dáhùn pé, “Ìwọ náà mọ̀ bí mo ti sìn ọ́ ati bí àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ ti ṣe dáradára lọ́wọ́ mi.