Jẹnẹsisi 20:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.”

4. Ṣugbọn Abimeleki kò tíì bá Sara lòpọ̀ rárá, ó bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, o wá lè pa àwọn eniyan aláìṣẹ̀ bí?

5. Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.”

6. Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án.

7. Ǹjẹ́ nisinsinyii, dá obinrin náà pada fún ọkọ rẹ̀, nítorí pé wolii ni ọkunrin náà yóo gbadura fún ọ, o óo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá dá a pada, mọ̀ dájú pé o óo kú, àtìwọ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ.”

8. Abimeleki yára dìde ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ó pe gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ jọ, ó ro gbogbo nǹkan wọnyi fún wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

9. Abimeleki bá pe Abrahamu, ó bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe wá báyìí? Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́ tí o fi ti ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí sí èmi ati ìjọba mi lọ́rùn? Ohun tí o ṣe sí mi yìí kò dára rárá!”

10. Ó bi Abrahamu pé, “Kí ni èrò rẹ gan-an, tí o fi ṣe ohun tí o ṣe yìí?”

11. Abrahamu dáhùn, ó ní, “Ohun tí ó mú mi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé, mo rò pé kò sí ìbẹ̀rù Ọlọrun níhìn-ín rárá ni, ati pé wọn yóo tìtorí aya mi pa mí.

12. Ati pé, arabinrin mi ni nítòótọ́, bí ó ṣe jẹ́ nìyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìyá kan náà ni ó bí wa, ọmọ baba kan ni wá kí ó tó di aya mi.

Jẹnẹsisi 20