25. Kí á má rí i pé o ṣe irú ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀! Kí o pa olódodo run pẹlu àwọn eniyan burúkú? Ṣé kò ní sí ìyàtọ̀ láàrin ìpín àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn olódodo ni? A kò gbọdọ̀ gbọ́ ọ. Ìwọ onídàájọ́ gbogbo ayé kò ha ní ṣe ẹ̀tọ́ bí?”
26. OLUWA dáhùn, ó ní, “Bí mo bá rí aadọta olódodo ninu ìlú Sodomu, n óo dá gbogbo ìlú náà sí nítorí tiwọn.”
27. Abrahamu tún sọ fún OLUWA pé, “Jọ̀wọ́, dárí àfojúdi mi jì mí, èmi eniyan lásán, nítorí n kò ní ẹ̀tọ́ láti bá ìwọ OLUWA jiyàn?
28. Ṣugbọn, ó ṣeéṣe pé aadọta tí mo wí lè dín marun-un, ṣé nítorí eniyan marun-un tí ó dín, o óo pa ìlú náà run?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí olódodo marundinlaadọta n kò ní pa ìlú náà run.”
29. Ó tún bèèrè pé, “Bí a bá rí ogoji ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn, ó ní, “N kò ní pa á run nítorí ogoji eniyan náà.”
30. Ó bá tún wí pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, bí a bá rí ọgbọ̀n eniyan ńkọ́?” OLUWA dáhùn pé, “Bí mo bá rí ọgbọ̀n olódodo, n kò ní pa ìlú náà run.”
31. Ó tún dáhùn pé “Jọ̀wọ́ dárí àfojúdi mi jì mí nítorí ọ̀rọ̀ mi, bí a bá rí ogún eniyan ńkọ́?” OLUWA tún dáhùn pé, “Nítorí ti ogún eniyan, n kò ní pa á run.”
32. Abrahamu tún dáhùn pé, “OLUWA, jọ̀wọ́ má bínú sí mi, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí ni ó kù tí n óo sọ̀rọ̀. Bí a bá rí eniyan mẹ́wàá ńkọ́?”OLUWA tún dá a lóhùn pé, “N kò ní pa á run nítorí ti eniyan mẹ́wàá.”