18. Nígbà tí Pelegi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.
19. Ó tún gbé igba ọdún ó lé mẹsan-an (209) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
20. Nígbà tí Reu di ẹni ọdún mejilelọgbọn ni ó bí Serugi.
21. Ó tún gbé igba ọdún ó lé meje (207) sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Serugi, ó sì tún bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
22. Nígbà tí Serugi di ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.
23. Ó tún gbé igba (200) ọdún sí i láyé lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
24. Nígbà tí Nahori di ẹni ọdún mọkandinlọgbọn ni ó bí Tẹra.
25. Ó tún gbé igba ọdún ó lé mọkandinlogun (219) sí i láyé, ó sì bí àwọn ọmọ mìíràn lọkunrin ati lobinrin.
26. Nígbà tí Tẹra di ẹni aadọrin ọdún ni ó bí Abramu, Nahori, ati Harani.
27. Àkọsílẹ̀ ìran Tẹra nìyí: Tẹra ni baba Abramu, Nahori ati Harani. Harani sì ni baba Lọti.
28. Harani kú ṣáájú Tẹra, baba rẹ̀, Uri ìlú rẹ̀, tí ó wà ní ilẹ̀ Kalidea ni ó kú sí.