6. Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára.
7. Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀.
8. Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá.
9. Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun.