1. OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Mo lòdì sí ọ́, ìwọ Gogu, ìwọ tí o jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali.
2. N óo yí ọ pada, n óo lé ọ siwaju, n óo mú ọ wá láti òpin ìhà àríwá, o óo wá dojú kọ àwọn òkè Israẹli.
3. Lẹ́yìn náà, n óo gbọn ọrun rẹ dànù lọ́wọ́ òsì rẹ; n óo sì gbọn ọfà bọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ.
4. Ìwọ, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo kú lórí àwọn òkè Israẹli. N óo fi yín ṣe oúnjẹ fún oniruuru àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko burúkú.