1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ òkè Seiri, kí o sì fi àsọtẹ́lẹ̀ bá a wí.
3. Wí fún un pé OLUWA Ọlọrun ní,‘Wò ó! Mo lòdì sí ọ,ìwọ Òkè Seiri.N óo nawọ́ ibinu sí ọ,n óo sọ ọ́ di ahoro ati aṣálẹ̀.
4. N óo sọ àwọn ìlú rẹ di aṣálẹ̀ìwọ pàápàá yóo sì di ahoro;o óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
5. “ ‘Nítorí pé ò ń fẹ́ràn ati máa ṣe ọ̀tá lọ títí, o sì fa àwọn ọmọ Israẹli fún ogun pa nígbà tí ìṣòro dé bá wọn, tí wọn ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.