Isikiẹli 27:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Àwọn oníṣòwò Ṣeba ati ti Raama náà a máa bá ọ ra ọjà, oríṣìíríṣìí turari olóòórùn dídùn ati òkúta olówó iyebíye ati wúrà ni wọ́n fi ń ṣe pàṣípààrọ̀ ọjà lọ́wọ́ rẹ.

23. Àwọn ará Harani, Kane, Edẹni, Aṣuri ati Kilimadi ń bá ọ ṣòwò.

24. Wọ́n ń kó ojúlówó ẹ̀wù aṣọ aláwọ̀ aró wá tà fún ọ, ati aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, ati ẹni tí ó ní oríṣìíríṣìí àwọ̀, tí wọ́n fi ìko hun.

25. Àwọn ọkọ̀ Taṣiṣi ní ń bá ọ ru ọjà rẹ lọ ta.Ọjà kún inú rẹ,ẹrù rìn ọ́ mọ́lẹ̀ láàrin omi òkun.

26. Àwọn tí ń wà ọ́ ti tì ọ́ sí ààrin agbami òkun.Atẹ́gùn ńlá ti dà ọ́ nù láàrin agbami òkun.

27. Gbogbo ọrọ̀ rẹ, ati gbogbo ọjà olówó iyebíye rẹ,àwọn tí ń tu ọkọ̀ rẹ ati àwọn tí ń darí rẹ;àwọn tí ń fi ọ̀dà dí ihò ara ọkọ̀ rẹati àwọn tí ń bá ọ ṣòwò.Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ ati àwọn èrò tí ó wà ninu rẹ,ni yóo rì sí ààrin gbùngbùn òkun, ní ọjọ́ ìparun rẹ.

28. Gbogbo èbúté yóo mì tìtìnígbà tí àwọn tí wọn ń tọ́ ọkọ̀ rẹ bá kígbe.

29. Gbogbo àwọn atukọ̀ ni yóo jáde kúrò ninu ọkọ̀.Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ninu ọkọ̀ati àwọn tí ń darí ọkọ̀yóo dúró ní èbúté.

30. Wọn óo gbé ohùn sókè sí ọ,wọn óo sun ẹkún kíkan kíkan.Wọn óo da erùpẹ̀ sórí wọn,wọn óo yíra mọ́lẹ̀ ninu eérú.

Isikiẹli 27